Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ

ẸKISODU 15:1-27

bible-1108074__340.png

[1]NIGBANA ni Mose ati awọn ọmọ Israeli kọ orin yi si OLUWA nwọn si wipe, Emi o kọrin si OLUWA, nitoriti o pọ̀ li ogo: ati ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.
[2]OLUWA li agbara ati orin mi, on li o si di ìgbala mi: eyi li Ọlọrun mi, emi o si fi ìyin fun u; Ọlọrun baba mi, emi o gbé e leke.
[3]Ologun li OLUWA; OLUWA li orukọ rẹ̀.
[4]Kẹkẹ́ Farao ati ogun rẹ̀ li o mu wọ̀ inu okun: awọn ãyo olori ogun rẹ̀ li o si rì ninu Okun Pupa.
[5]Ibú bò wọn mọlẹ: nwọn rì si isalẹ bi okuta.
[6]OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ li ogo ninu agbara: OLUWA, ọwọ́ ọtún rẹ fọ́ ọtá tútu.
[7]Ati ni ọ̀pọlọpọ ọlá rẹ ni iwọ bì awọn ti o dide si ọ ṣubu; iwọ rán ibinu rẹ, ti o run wọn bi akemọlẹ idi koriko.
[8]Ati nipa ẽmi imu rẹ, li omi si fi wọjọ pọ̀, ìṣan omi dide duro gangan bi ogiri; ibú si dìlu lãrin okun.
[9]Ọtá wipe, Emi o lepa, emi o bá wọn, emi o pín ikogun: a o tẹ́ ifẹkufẹ mi lọrùn lara wọn; emi o fà dà mi yọ, ọwọ́ mi ni yio pa wọn run.
[10]Iwọ si mu afẹfẹ rẹ fẹ́, okun bò wọn mọlẹ: nwọn rì bi ojé ninu omi nla.
[11]Tali o dabi iwọ, OLUWA, ninu awọn alagbara? tali o dabi iwọ, ologo ni mimọ́, ẹlẹru ni iyìn, ti nṣe ohun iyanu?
[12]Iwọ nà ọwọ́ ọtún rẹ, ilẹ gbe wọn mì.
[13]Ninu ãnu rẹ ni iwọ fi ṣe amọ̀na awọn enia na ti iwọ ti rapada: iwọ si nfi agbara rẹ tọ́ wọn lọ si ibujoko mimọ́ rẹ.
[14]Awọn enia gbọ́, nwọn warìri; ikãnu si mú awọn olugbe Palestina.
[15]Nigbana li ẹnu yà awọn balẹ Edomu; iwarìri si mú awọn alagbara Moabu: gbogbo awọn olugbe Kenaani yọ́ dànu.
[16]Ibẹru-bojo mú wọn; nipa titobi apa rẹ nwọn duro jẹ bi okuta; titi awọn enia rẹ fi rekọja, OLUWA, titi awọn enia rẹ ti iwọ ti rà fi rekọja.
[17]Iwọ o mú wọn wọle, iwọ o si gbìn wọn sinu oke ilẹ-iní rẹ, OLUWA, ni ibi ti iwọ ti ṣe fun ara rẹ, lati mã gbé, OLUWA; ni ibi mimọ́ na, ti ọwọ́ rẹ ti gbekalẹ.
[18]OLUWA yio jọba lai ati lailai.
[19]Nitori ẹṣin Farao wọ̀ inu okun lọ, pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀ ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀, OLUWA si tun mú omi okun pada si wọn lori; ṣugbọn awọn ọmọ Israeli rìn ni ilẹ gbigbẹ lãrin okun.
[20]Ati Miriamu wolĩ obinrin, arabinrin Aaroni, o mú ìlu li ọwọ́ rẹ̀: gbogbo awọn obinrin si jade tẹle e ti awọn ti ìlu ati ijó.
[21]Miriamu si da wọn li ohùn pe, Ẹ kọrin si OLUWA nitoriti o pọ̀ li ogo; ẹṣin ati ẹlẹṣin on li o bì ṣubu sinu okun.
[22]Bẹ̃ni Mose mú Israeli jade lati Okun Pupa wá, nwọn si jade lọ si ijù Ṣuri; nwọn si lọ ni ìrin ijọ́ mẹta ni ijù na, nwọn kò si ri omi.
[23]Nigbati nwọn dé Mara, nwọn ko le mu ninu omi Mara, nitoriti o korò; nitorina li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Mara.
[24]Awọn enia na si nkùn si Mose wipe, Kili awa o mu?
[25]O si kepè OLUWA; OLUWA si fi igi kan hàn a, nigbati o si sọ ọ sinu omi na, omi si di didùn. Nibẹ̀ li o si gbé ṣe ofin ati ìlana fun wọn, nibẹ̀ li o si gbé dán wọn wò;
[26]O si wipe, Bi iwọ o ba tẹtisilẹ gidigidi si ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o ba si ṣe eyiti o tọ́ li oju rẹ̀, ti iwọ o ba si fetisi ofin rẹ̀, ti iwọ o ba si pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́, emi ki yio si fi ọkan ninu àrun wọnni ti mo múwa sara awọn ara Egipti si ọ lara: nitori emi li OLUWA ti o mu ọ lara dá.
[27]Nwọn si dé Elimu, nibiti kanga omi mejila gbé wà, ati ãdọrin ọpẹ: nwọn si dó si ìha omi wọnni nibẹ̀.

H2
H3
H4
3 columns
2 columns
1 column
Join the conversation now
Logo
Center