Oun ti abaje si kun
Ni yoo so emi to
Oun ti a ba fi ko omo eni
Ni yio di Ogun fun un
Eda to fomo re sile lai ko logbon
To nko ile,to si nko asoojo
Ko ranti pe ile yoo di teni eleni
Aso yoo di Ogun ebi elebi gbogbo
Tabi tani ko mo daju wipe
Omo ti a koo to ni yoo gbele tako ta
Tabi ni igba ti omo ba ya olee eniyan
Ti ko jaa fafa laye nko
Kinni yio tun da,lehin agirinle
Omo ti nrungun, omo palanta omo
Omo apa ti ko tile ta
Omo ti n ta oun gbogbo ti baba nijeun
Ejeka ranju wo ka fi ko omo eni
Ka roju ko won logbon
Ronju koroko!!!